Yorùbá Bibeli

Luk 3:20-28 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. O fi eyi pari gbogbo rẹ̀ niti o fi Johanu sinu tubu.

21. Nigbati a si baptisi awọn enia gbogbo tan, o si ṣe, a baptisi Jesu pẹlu, bi o ti ngbadura, ọrun ṣí silẹ̀,

22. Ẹmí Mimọ́ si sọkalẹ si ori rẹ̀ li àwọ àdaba, ohùn kan si ti ọrun wá, ti o wipe, Iwọ ni ayanfẹ ọmọ mi; ẹniti inu mi dùn si gidigidi.

23. Jesu tikararẹ̀ nto bi ẹni ìwọn ọgbọ̀n ọdún, o jẹ (bi a ti fi pè) ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Eli,

24. Ti iṣe ọmọ Mattati, ti iṣe ọmọ Lefi, ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Janna, ti iṣe ọmọ Josefu,

25. Ti iṣe ọmọ Mattatai, ti iṣe ọmọ Amosi, ti iṣe ọmọ Naumu, ti iṣe ọmọ Esli, ti iṣe ọmọ Naggai,

26. Ti iṣe ọmọ Maati, ti iṣe ọmọ Mattatia, ti iṣe ọmọ Simei, ti iṣe ọmọ Josefu, ti iṣe ọmọ Juda,

27. Ti iṣe ọmọ Joanna, ti iṣe ọmọ Resa, ti iṣe ọmọ Sorobabeli, ti iṣe ọmọ Salatieli, ti iṣe ọmọ Neri,

28. Ti iṣe ọmọ Melki, ti iṣe ọmọ Addi, ti iṣe ọmọ Kosamu, ti iṣe ọmọ Elmodamu, ti iṣe ọmọ Eri,