Yorùbá Bibeli

Luk 20:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, ni ijọ kan li ọjọ wọnni, bi o ti nkọ́ awọn enia ni tẹmpili ti o si nwasu ihinrere, awọn olori alufa, ati awọn pẹlu awọn agbagbà dide sí i,

2. Nwọn si wi fun u pe, Sọ fun wa, aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tabi tali o fun ọ li aṣẹ yi?

3. O si dahùn o si wi fun wọn pe, Emi pẹlu yio si bi nyin lẽre ọ̀rọ kan; ẹ sọ fun mi.

4. Baptismu ti Johanu, lati ọrun wá ni tabi lọdọ enia?

5. Nwọn si ba ara wọn gbèro wipe, Bi awa ba wipe, Lati ọrun wá ni; on o wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi gbà a gbọ́?

6. Ṣugbọn bi awa ba si wipe, Lati ọdọ enia; gbogbo enia ni yio sọ wa li okuta; nitori nwọn gbagbọ pe, woli ni Johanu.

7. Nwọn si dahùn wipe, nwọn kò mọ̀ ibiti o ti wá.

8. Jesu si wi fun wọn pe, Njẹ emi ki yio wi fun nyin aṣẹ ti emi fi nṣe nkan wọnyi.

9. Nigbana li o bẹ̀rẹ si ipa owe yi fun awọn enia pe; ọkunrin kan gbìn ọgba ajara kan, o si fi ṣe agbatọju fun awọn àgbẹ, o si lọ si àjo fun igba pipẹ.

10. Nigbati o si di akokò, o rán ọmọ-ọdọ rẹ̀ kan si awọn àgbẹ na, ki nwọn ki o le fun u ninu eso ọgba ajara na: ṣugbọn awọn àgbẹ lù u, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.

11. O si tún rán ọmọ-ọdọ miran: nwọn si lù u pẹlu, nwọn si jẹ ẹ nìya, nwọn si rán a pada lọwọ ofo.