Yorùbá Bibeli

Luk 19:9-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.

10. Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.

11. Nigbati nwọn si ngbọ́ nkan wọnyi, o fi ọ̀rọ kún u, o si pa owe kan, nitoriti o sunmọ Jerusalemu, ati nitoriti nwọn nrò pe, ijọba Ọlọrun yio farahàn nisisiyi.

12. O si wipe, ọkunrin ọlọlá kan rè ilu òkere lọ igbà ijọba fun ara rẹ̀, ki o si pada.

13. O si pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ mẹwa, o fi mina mẹwa fun wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã ṣowo titi emi o fi de.