Yorùbá Bibeli

Luk 19:5-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.

6. O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ̀ gbà a.

7. Nigbati nwọn si ri i, gbogbo wọn nkùn, wipe, O lọ iwọ̀ lọdọ ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ.

8. Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.

9. Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.

10. Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.

11. Nigbati nwọn si ngbọ́ nkan wọnyi, o fi ọ̀rọ kún u, o si pa owe kan, nitoriti o sunmọ Jerusalemu, ati nitoriti nwọn nrò pe, ijọba Ọlọrun yio farahàn nisisiyi.

12. O si wipe, ọkunrin ọlọlá kan rè ilu òkere lọ igbà ijọba fun ara rẹ̀, ki o si pada.

13. O si pè awọn ọmọ-ọdọ rẹ̀ mẹwa, o fi mina mẹwa fun wọn, o si wi fun wọn pe, Ẹ mã ṣowo titi emi o fi de.

14. Ṣugbọn awọn ọlọ̀tọ ilu rẹ̀ korira rẹ̀, nwọn si rán ikọ̀ tẹ̀le e, wipe, Awa kò fẹ ki ọkunrin yi jọba lori wa.

15. O si ṣe, nigbati o gbà ijọba tan, ti o pada de, o paṣẹ pe, ki a pè awọn ọmọ-ọdọ wọnni wá sọdọ rẹ̀, ti on ti fi owo fun nitori ki o le mọ̀ iye ere ti olukuluku fi iṣowo jẹ.