Yorùbá Bibeli

Luk 19:43-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

43. Nitori ọjọ mbọ̀ fun ọ, ti awọn ọtá rẹ yio wà yàra ká ọ, nwọn o si yi ọ ká, nwọn o si ká ọ mọ́ niha gbogbo.

44. Nwọn o si wó ọ palẹ bẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; nwọn kì yio si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitoriti iwọ ko mọ̀ ọjọ ìbẹwo rẹ.

45. O si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o si bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ninu rẹ̀ sode;

46. O si wi fun wọn pe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Ile mi yio jẹ ile adura; ṣugbọn ẹnyin ti sọ ọ di ihò olè.

47. O si nkọ́ni lojojumọ ni tẹmpili. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn olori awọn enia nwá ọ̀na ati pa a run,

48. Nwọn kò si ri bi nwọn iba ti ṣe: nitori gbogbo enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ̀rọ rẹ̀.