Yorùbá Bibeli

Luk 19:39-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Awọn kan ninu awọn Farisi li awujọ si wi fun u pe, Olukọni ba awọn ọmọ-ẹhin rẹ wi.

40. O si da wọn lohùn, o wi fun wọn pe, Mo wi fun nyin, Bi awọn wọnyi ba pa ẹnu wọn mọ́, awọn okuta yio kigbe soke.

41. Nigbati o si sunmọ etile, o ṣijuwò ilu na, o sọkun si i lori,

42. O nwipe, Ibaṣepe iwọ mọ̀, loni yi, ani iwọ, ohun ti iṣe ti alafia rẹ! ṣugbọn nisisiyi nwọn pamọ́ kuro li oju rẹ.

43. Nitori ọjọ mbọ̀ fun ọ, ti awọn ọtá rẹ yio wà yàra ká ọ, nwọn o si yi ọ ká, nwọn o si ká ọ mọ́ niha gbogbo.

44. Nwọn o si wó ọ palẹ bẹrẹ, ati awọn ọmọ rẹ ninu rẹ; nwọn kì yio si fi okuta kan silẹ lori ara wọn; nitoriti iwọ ko mọ̀ ọjọ ìbẹwo rẹ.

45. O si wọ̀ inu tẹmpili lọ, o si bẹ̀rẹ si ilé awọn ti ntà ninu rẹ̀ sode;

46. O si wi fun wọn pe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Ile mi yio jẹ ile adura; ṣugbọn ẹnyin ti sọ ọ di ihò olè.

47. O si nkọ́ni lojojumọ ni tẹmpili. Ṣugbọn awọn olori alufa, ati awọn akọwe, ati awọn olori awọn enia nwá ọ̀na ati pa a run,

48. Nwọn kò si ri bi nwọn iba ti ṣe: nitori gbogbo enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ̀rọ rẹ̀.