Yorùbá Bibeli

Luk 19:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. JESU si wọ̀ Jeriko lọ, o si nkọja lãrin rẹ̀.

2. Si kiyesi i, ọkunrin kan wà ti a npè ni Sakeu, o si jẹ olori agbowode kan, o si jẹ ọlọrọ̀.

3. O si nfẹ lati ri ẹniti Jesu iṣe; kò si le ri i, nitori ọ̀pọ enia, ati nitoriti on ṣe enia kukuru.

4. O si sure siwaju, o gùn ori igi sikamore kan, ki o ba le ri i: nitoriti yio kọja lọ niha ibẹ̀.

5. Nigbati Jesu si de ibẹ̀, o gbé oju soke, o si ri i, o si wi fun u pe, Sakeu, yara, ki o si sọkalẹ; nitori emi kò le ṣaiwọ ni ile rẹ loni.

6. O si yara, o sọkalẹ, o si fi ayọ̀ gbà a.

7. Nigbati nwọn si ri i, gbogbo wọn nkùn, wipe, O lọ iwọ̀ lọdọ ọkunrin ti iṣe ẹlẹṣẹ.

8. Sakeu si dide, o si wi fun Oluwa pe, Wo o, Oluwa, àbọ ohun ini mi ni mo fifun talakà; bi mo ba si fi ẹ̀sun eke gbà ohun kan lọwọ ẹnikẹni, mo san a pada ni ilọpo mẹrin.

9. Jesu si wi fun u pe, Loni ni igbala wọ̀ ile yi, niwọnbi on pẹlu ti jẹ ọmọ Abrahamu.

10. Nitori Ọmọ-enia de lati wá awọn ti o nù kiri, ati lati gbà wọn là.