Yorùbá Bibeli

Luk 18:23-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Nigbati o si gbọ́ eyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi: nitoriti o li ọrọ̀ pipo.

24. Nigbati Jesu ri i pe, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi, o ni, Yio ti ṣoro to fun awọn ti o li ọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun!

25. Nitori o rọrun fun ibakasiẹ lati gbà oju abẹrẹ wọle, jù fun ọlọrọ̀ lati wọ̀ ijọba Ọlọrun lọ.

26. Awọn ti o si gbọ́ wipe, Njẹ tali o ha le là?

27. O si wipe, Ohun ti o ṣoro lọdọ enia, kò ṣoro lọdọ Ọlọrun.

28. Peteru si wipe, Sawõ, awa ti fi tiwa silẹ, a si tọ̀ ọ lẹhin.

29. O si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, Kò si ẹniti o fi ile, tabi aya, tabi ará, tabi õbi, tabi ọmọ silẹ, nitori ijọba Ọlọrun,

30. Ti kì yio gba ilọpo pipọ si i li aiye yi, ati li aiye ti mbọ̀ ìye ainipẹkun.

31. Nigbana li o pè awọn mejila sọdọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Sawõ, awa ngòke lọ si Jerusalemu, a o si mu ohun gbogbo ṣẹ, ti a ti kọ lati ọwọ́ awọn woli wá, nitori Ọmọ-enia.

32. Nitori a o fi i le awọn Keferi lọwọ, a o fi i ṣe ẹlẹyà, a o si fi i ṣe ẹsin, a o si tutọ́ si i lara:

33. Nwọn o si nà a, nwọn o si pa a: ni ijọ kẹta yio si jinde.

34. Ọkan ninu nkan wọnyi kò si yé wọn: ọ̀rọ yi si pamọ́ fun wọn, bẹ̃ni nwọn ko si mọ̀ ohun ti a wi.

35. O si ṣe, bi on ti sunmọ Jeriko, afọju kan joko lẹba ọ̀na o nṣagbe:

36. Nigbati o gbọ́ ti ọpọ́ enia nkọja lọ, o bère pe, kili ã le mọ̀ eyi si.