Yorùbá Bibeli

Luk 10:16-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Ẹniti o ba gbọ́ ti nyin, o gbọ́ ti emi: ẹniti o ba si kọ̀ nyin, o kọ̀ mi; ẹniti o ba si kọ̀ mi, o kọ̀ ẹniti o rán mi.

17. Awọn adọrin na si fi ayọ̀ pada, wipe, Oluwa, awọn ẹmi èṣu tilẹ foribalẹ fun wa li orukọ rẹ.

18. O si wi fun wọn pe, Emi ri Satani ṣubu bi manamana lati ọrun wá.

19. Kiyesi i, emi fun nyin li aṣẹ lati tẹ̀ ejò ati akẽkẽ mọlẹ, ati lori gbogbo agbara ọtá: kò si si ohunkan bi o ti wù ki o ṣe, ti yio pa-nyin-lara.

20. Ṣugbọn ki ẹ máṣe yọ̀ si eyi, pe, awọn ẹmi nforibalẹ fun nyin; ṣugbọn ẹ kuku yọ̀, pe, a kọwe orukọ nyin li ọrun.

21. Ni wakati kanna Jesu yọ̀ ninu Ẹmi Mimọ́ o si wipe, Mo dupẹ lọwọ rẹ, Baba, Oluwa ọrun on aiye, pe, iwọ pa nkan wọnyi mọ́ kuro lọdọ awọn ọlọ́gbọn ati amoye, iwọ si fi wọn hàn fun awọn ọmọ-ọwọ: bẹ̃ni, Baba, bẹ̃li o sá yẹ li oju rẹ.

22. Ohun gbogbo li a fifun mi lati ọdọ Baba mi wá: kò si si ẹniti o mọ̀ ẹniti Ọmọ iṣe, bikoṣe Baba; ati ẹniti Baba iṣe, bikoṣe Ọmọ, ati ẹnikẹni ti o ba si wù Ọmọ lati fi i hàn fun.

23. O si yipada si awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ li apakan, o ni, Ibukún ni fun ojú ti nri ohun ti ẹnyin nri:

24. Nitori mo wi fun nyin, Woli ati ọba pipọ li o nfẹ lati ri ohun ti ẹnyin nri, nwọn kò si ri wọn, ati lati gbọ ohun ti ẹnyin ngbọ́, nwọn ko si gbọ́ wọn,

25. Si kiyesi i, amofin kan dide, o ndán a wò, o ni, Olukọni, kili emi o ṣe ki emi ki o le jogún iyè ainipẹkun?

26. O si bi i pe, Kili a kọ sinu iwe ofin? bi iwọ ti kà a?

27. O si dahùn wipe, Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.

28. O si wi fun u pe, Iwọ dahùn rere: ṣe eyi, iwọ o si yè.

29. Ṣugbọn o nfẹ lati dá ara rẹ̀ lare, o wi fun Jesu pe, Tani ha si li ẹnikeji mi?