Yorùbá Bibeli

Luk 1:39-49 Yorùbá Bibeli (YCE)

39. Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda;

40. O si wọ̀ ile Sakariah lọ o si ki Elisabeti.

41. O si ṣe, nigbati Elisabeti gbọ́ kikí Maria, ọlẹ̀ sọ ninu rẹ̀; Elisabeti si kún fun Ẹmí Mimọ́:

42. O si ke li ohùn rara, o si wipe, Alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin, alabukun-fun si ni fun ọmọ inu rẹ.

43. Nibo si li eyi ti wá ba mi, ti iya Oluwa mi iba fi tọ̀ mi wá?

44. Sawò o, bi ohùn kikí rẹ ti bọ́ si mi li etí, ọlẹ̀ sọ ninu mi fun ayọ̀.

45. Alabukun-fun si li ẹniti o gbagbọ́: nitori nkan wọnyi ti a ti sọ fun u lati ọdọ Oluwa wá yio ṣẹ.

46. Maria si dahùn, o ni, Ọkàn mi yìn Oluwa logo,

47. Ẹmí mi si yọ̀ si Ọlọrun Olugbala mi.

48. Nitoriti o ṣijuwò ìwa irẹlẹ ọmọbinrin ọdọ rẹ̀: sá wò o, lati isisiyi lọ gbogbo iran enia ni yio ma pè mi li alabukunfun.

49. Nitori ẹniti o li agbara ti ṣe ohun ti o tobi fun mi; mimọ́ si li orukọ rẹ̀.