Yorùbá Bibeli

Jud 1:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Olufẹ, nigbati mo fi aisimi gbogbo kọwe si nyin niti igbala ti iṣe ti gbogbo enia, nko gbọdọ ṣaima kọwé si nyin, ki n si gbà nyin niyanju lati mã ja gidigidi fun igbagbọ́, ti a ti fi lé awọn enia mimọ́ lọwọ lẹ̃kanṣoṣo.

4. Nitori awọn enia kan mbẹ ti nwọn nyọ́ wọle, awọn ẹniti a ti yàn lati igbà atijọ si ẹbi yi, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti nyi ore-ọfẹ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti nwọn si nsẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo na, ani Jesu Kristi Oluwa.

5. Njẹ emi nfẹ lati rán nyin leti bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ gbogbo rẹ̀ lẹ̃kan ri, pe Oluwa, nigbati o ti gbà awọn enia kan là lati ilẹ Egipti wá, lẹhinna o run awọn ti kò gbagbọ́.

6. Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì.

7. Ani bi Sodomu ati Gomorra, ati awọn ilu agbegbe wọn, ti fi ara wọn fun àgbere iṣe bakanna, ti nwọn si ntẹle ara ajeji lẹhin, awọn li a fi lelẹ bi apẹrẹ, nwọn njìya iná ainipẹkun.

8. Bakanna ni awọn wọnyi pẹlu nsọ ara di ẽri ninu àlá wọn, nwọn si ngan ijoye, nwọn si nsọ̀rọ buburu si awọn ọlọlá.

9. Ṣugbọn Mikaeli, olori awọn angẹli, nigbati o mba Èṣu jà, ti o nṣì jijakadi nitori okú Mose, kò si gbọdọ sọ ọ̀rọ-odi si i, ṣugbọn o wipe, Oluwa ni yio ba ọ wi.