1. BI o si ti nkọja lọ, o ri ọkunrin kan ti o fọju lati igba ibí rẹ̀ wá.
2. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe. Olukọni, tani dẹṣẹ, ọkunrin yi tabi awọn obi rẹ̀, ti a fi bi i li afọju?
3. Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.
4. Emi kò le ṣe alaiṣe iṣẹ ẹniti o rán mi, nigbati iṣe ọsan: oru mbọ̀ wá nigbati ẹnikan kì o le ṣe iṣẹ.
5. Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.
6. Nigbati o ti wi bẹ̃ tan, o tutọ́ silẹ, o si fi itọ́ na ṣe amọ̀, o si fi amọ̀ na pa oju afọju na,