Yorùbá Bibeli

Joh 8:20-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.

21. Nitorina o tun wi fun wọn pe, Emi nlọ, ẹnyin yio si wá mi, ẹ ó si kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: ibiti emi gbe nlọ, ẹnyin kì ó le wá.

22. Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá.

23. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi.

24. Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin.

25. Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe.

26. Mo ni ohun pupọ̀ lati sọ, ati lati ṣe idajọ nipa nyin: ṣugbọn olõtọ li ẹniti o ran mi, ohun ti emi si ti gbọ lati ọdọ rẹ̀ wá, nwọnyi li emi nsọ fun araiye.

27. Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn.

28. Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Nigbati ẹ ba gbé Ọmọ-enia soke, nigbana li ẹ o mọ̀ pe, emi ni, ati pe emi kò dá ohunkohun ṣe fun ara mi; ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi nsọ nkan wọnyi.

29. Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo.

30. Bi o ti nsọ nkan wọnyi, ọ̀pọ enia gbà a gbọ́.

31. Nitorina Jesu wi fun awọn Ju ti o gbà a gbọ́ pe, Bi ẹnyin ba duro ninu ọ̀rọ mi, nigbana li ẹnyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitõtọ.

32. Ẹ ó si mọ̀ otitọ, otitọ yio si sọ nyin di omnira.

33. Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira?

34. Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.

35. Ẹrú kì si igbé ile titilai: Ọmọ ni igbe ile titilai.