11. Niti idajọ, nitoriti a ti ṣe idajọ alade aiye yi.
12. Mo ni ohun pipọ lati sọ fun nyin pẹlu, ṣugbọn ẹ kò le gbà wọn nisisiyi.
13. Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin.
14. On o ma yìn mi logo: nitoriti yio gbà ninu ti emi, yio si ma sọ ọ fun nyin.
15. Ohun gbogbo ti Baba ni temi ni: nitori eyi ni mo ṣe wipe, on ó gbà ninu temi, yio si sọ ọ fun nyin.
16. Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.
17. Nitorina omiran ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ mba ara wọn sọ pe, Kili eyi ti o nwi fun wa yi, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi: ati, Nitoriti emi nlọ sọdọ Baba?
18. Nitorina nwọn wipe, Kili eyi ti o wi yi, Nigba diẹ? awa kò mọ̀ ohun ti o wi.
19. Jesu sá ti mọ̀ pe, nwọn nfẹ lati bi on lẽre, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin mbi ara nyin lẽre niti eyi ti mo wipe, Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹnyin o si ri mi?