2. Gbogbo ẹká ninu mi ti kò ba so eso, on a mu u kuro: gbogbo ẹka ti o ba si so eso, on a wẹ̀ ẹ mọ́, ki o le so eso si i.
3. Ẹnyin mọ́ nisisiyi nitori ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin.
4. Ẹ mã gbé inu mi, emi o si mã gbé inu nyin. Gẹgẹ bi ẹka kò ti le so eso fun ara rẹ̀, bikoṣepe o ba ngbé inu àjara, bẹ̃li ẹnyin, bikoṣepe ẹ ba ngbé inu mi.
5. Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan.
6. Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna.
7. Bi ẹnyin ba ngbé inu mi, ti ọ̀rọ mi ba si ngbé inu nyin, ẹ ó bère ohunkohun ti ẹ ba fẹ, a o si ṣe e fun nyin.
8. Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi.
9. Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹ̃li emi si fẹ nyin: ẹ duro ninu ifẹ mi.
10. Bi ẹnyin ba pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi; gẹgẹ bi emi ti pa ofin Baba mi mọ́, ti mo si duro ninu ifẹ rẹ̀.
11. Nkan wọnyi ni mo ti sọ fun nyin, ki ayọ̀ mi ki o le wà ninu nyin, ati ki ayọ̀ nyin ki o le kún.
12. Eyi li ofin mi, pe ki ẹnyin ki o fẹran ara nyin, gẹgẹ bi mo ti fẹràn nyin.
13. Ko si ẹnikan ti o ni ifẹ ti o tobi jù eyi lọ, pe ẹnikan fi ẹmí rẹ̀ lelẹ nitori awọn ọrẹ́ rẹ̀.
14. Ọrẹ́ mi li ẹnyin iṣẹ, bi ẹ ba ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun nyin.
15. Emi kò pè nyin li ọmọ-ọdọ mọ́; nitori ọmọ-ọdọ kò mọ̀ ohun ti oluwa rẹ̀ nṣe: ṣugbọn emi pè nyin li ọrẹ́; nitori ohun gbogbo ti mo ti gbọ́ lati ọdọ Baba mi wá, mo ti fi hàn fun nyin.
16. Ki iṣe ẹnyin li o yàn mi, ṣugbọn emi li o yàn nyin, mo si fi nyin sipo, ki ẹnyin ki o le lọ, ki ẹ si so eso, ati ki eso nyin le duro; ki ohunkohun ti ẹ ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, ki o le fi i fun nyin.