Yorùbá Bibeli

Joh 11:48-56 Yorùbá Bibeli (YCE)

48. Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ̃, gbogbo enia ni yio gbà a gbọ́: awọn ará Romu yio si wá gbà ilẹ ati orilẹ-ède wa pẹlu.

49. Ṣugbọn Kaiafa, ọkan ninu wọn, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na, o wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohunkohun rara.

50. Bẹ̃ni ẹ kò si ronu pe, o ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ède ki o má bà ṣegbé.

51. Ki iṣe fun ara rẹ̀ li o sọ eyi: ṣugbọn bi o ti jẹ olori alufa li ọdún na, o sọtẹlẹ pe, Jesu yio kú fun orilẹ-ède na:

52. Ki si iṣe kìki fun orilẹ-ède na nikan, ṣugbọn pẹlu ki o le kó awọn ọmọ Ọlọrun ti a ti funka kiri jọ li ọkanṣoṣo.

53. Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a.

54. Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.

55. Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́.

56. Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ?