Yorùbá Bibeli

Joṣ 6:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. O si ṣe, nigbati Joṣua wi fun awọn enia tán, awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje, kọja niwaju OLUWA nwọn si fọn ipè wọnni: apoti majẹmu OLUWA si tẹle wọn.

9. Awọn ti o hamọra si lọ niwaju awọn alufa, ti nfọn ipè, ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti lẹhin, awọn alufa nlọ nwọn si nfọn ipè.

10. Joṣua si paṣẹ fun awọn enia wipe, Ẹ kò gbọdọ hó bẹ̃li ẹ kò gbọdọ pariwo, bẹ̃li ọ̀rọ kan kò gbọdọ jade li ẹnu nyin, titi ọjọ́ ti emi o wi fun nyin pe, ẹ hó; nigbana li ẹnyin o hó.

11. Bẹ̃li o mu ki apoti OLUWA ki o yi ilu na ká, o yi i ká lẹ̃kan: nwọn si lọ si ibudó, nwọn si wọ̀ ni ibudó.

12. Joṣua si dide ni kùtukutu owurọ̀, awọn alufa si gbé apoti OLUWA.

13. Awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje niwaju apoti OLUWA nlọ titi, nwọn si nfọn ipè wọnni: awọn ti o hamọra-ogun nlọ niwaju wọn; ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti OLUWA lẹhin, awọn alufa si nfọn ipè bi nwọn ti nlọ.

14. Li ọjọ́ keji nwọn yi ilu na ká lẹ̃kan, nwọn si pada si ibudó: bẹ̃ni nwọn ṣe ni ijọ́ mẹfa.

15. O si ṣe ni ijọ́ keje, nwọn dide ni kùtukutu li afẹmọjumọ́, nwọn si yi ilu na ká gẹgẹ bi ti iṣaju lẹ̃meje: li ọjọ́ na nikanṣoṣo ni nwọn yi ilu na ká lẹ̃meje.

16. O si ṣe ni ìgba keje, nigbati awọn alufa fọn ipè, ni Joṣua wi fun awọn enia pe, Ẹ hó; nitoriti OLUWA ti fun nyin ni ilu na.

17. Ilu na yio si jẹ́ ìyasọtọ si OLUWA, on ati gbogbo ohun ti mbẹ ninu rẹ̀: kìki Rahabu panṣaga ni yio là, on ati gbogbo awọn ti mbẹ ni ile pẹlu rẹ̀, nitoriti o pa awọn onṣẹ ti a rán mọ́.

18. Ati ẹnyin, bi o ti wù ki o ri, ẹ pa ara nyin mọ́ kuro ninu ohun ìyasọtọ, ki ẹ má ba yà a sọ̀tọ tán ki ẹ si mú ninu ohun ìyasọtọ na; ẹnyin a si sọ ibudó Israeli di ifibu, ẹnyin a si mu iyọnu bá a.