Yorùbá Bibeli

Joṣ 6:5-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Yio si ṣe, nigbati nwọn ba fọn ipè jubeli kikan, nigbati ẹnyin ba si gbọ́ iró ipè na, gbogbo awọn enia yio si hó kũ; odi ilu na yio si wó lulẹ, bẹrẹ, awọn enia yio si gòke lọ tàra, olukuluku niwaju rẹ̀.

6. Joṣua ọmọ Nuni si pè awọn alufa, o si wi fun wọn pe, Ẹ gbé apoti majẹmu na, ki alufa meje ki o gbé ipè jubeli meje nì niwaju apoti OLUWA.

7. O si wi fun awọn enia pe, Ẹ kọja, ki ẹ si yi ilu na ká, ki awọn ti o hamọra ki o si kọja niwaju apoti OLUWA.

8. O si ṣe, nigbati Joṣua wi fun awọn enia tán, awọn alufa meje ti o gbé ipè jubeli meje, kọja niwaju OLUWA nwọn si fọn ipè wọnni: apoti majẹmu OLUWA si tẹle wọn.

9. Awọn ti o hamọra si lọ niwaju awọn alufa, ti nfọn ipè, ogun-ẹhin si ntọ̀ apoti lẹhin, awọn alufa nlọ nwọn si nfọn ipè.