Yorùbá Bibeli

Joṣ 19:20-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ati Rabbiti, Kiṣioni, ati Ebesi;

21. Ati Remeti, ati Eni-gannimu, ati Enhadda, ati Beti-passesi;

22. Àla na si dé Tabori, ati Ṣahasuma, ati Beti-ṣemeṣi; àla wọn yọ si Jordani: ilu mẹrindilogun pẹlu ileto wọn.

23. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Issakari gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi ati ileto wọn.

24. Ipín karun yọ fun ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn.

25. Àla wọn si ni Helkati, ati Hali, ati Beteni, ati Akṣafu;

26. Ati Allammeleki, ati Amadi, ati Miṣali; o si dé Karmeli ni ìha ìwọ-õrùn, ati Ṣihorilibnati;

27. O si ṣẹri lọ si ìha ìla-õrùn dé Beti-dagoni, o si dé Sebuluni, ati afonifoji Ifta-eli ni ìha ariwa dé Betemeki, ati Neieli; o si yọ si Kabulu li apa òsi,

28. Ati Ebroni, ati Rehobu, ati Hammoni, ati Kana, ani titi dé Sidoni nla;

29. Àla na si ṣẹri lọ si Rama, ati si Tire ilu olodi; àla na si ṣẹri lọ si Hosa; o si yọ si okun ni ìha Aksibu:

30. Ati Umma, ati Afeki, ati Rehobu: ilu mejilelogun pẹlu ileto wọn.

31. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Aṣeri gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọnyi pẹlu ileto wọn.

32. Ipín kẹfa yọ fun awọn ọmọ Naftali, ani fun awọn ọmọ Naftali gẹgẹ bi idile wọn.

33. Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Helefu, lati igi-oaku Saanannimu, ati Adami-nekebu, ati Jabneeli dé Lakkumu; o si yọ si Jordani.

34. Àla na si ṣẹri lọ sí ìha ìwọ-õrùn si Asnoti-taboru, o si ti ibẹ̀ lọ si Hukkoki; o si dé Sebuluni ni gusù, o si dé Aṣeri ni ìwọ-õrùn, ati Juda ni Jordani ni ìha ìla-õrùn.

35. Awọn ilu olodi si ni Siddimu, Seri, ati Hammati, Rakkati, ati Kinnereti;

36. Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru;

37. Ati Kedeṣi, ati Edrei, ati Eni-hasoru;

38. Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn.