Yorùbá Bibeli

Joṣ 19:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IPÍN keji yọ fun Simeoni, ani fun ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn; ilẹ-iní wọn si wà lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Juda.

2. Nwọn si ní Beeri-ṣeba, tabi Ṣeba, ati Molada, ni ilẹ-iní wọn;

3. Ati Hasari-ṣuali, ati Bala, ati Esemu;

4. Ati Eltoladi, ati Bẹtulu, ati Horma;

5. Ati Siklagi, ati Beti-markabotu, ati Hasari-susa;

6. Ati Beti-lebaotu, ati Ṣaruheni; ilu mẹtala pẹlu ileto wọn:

7. Aini, Rimmoni, ati Eteri, ati Aṣani; ilu mẹrin pẹlu ileto wọn:

8. Ati gbogbo ileto ti o yi ilu wọnyi ká dé Baalati-beeri, Rama ti Gusù. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni gẹgẹ bi idile wọn.

9. Ninu ipín awọn ọmọ Juda ni awọn ọmọ Simeoni ni ilẹ-iní: nitori ipín awọn ọmọ Juda pọ̀ju fun wọn: nitorina ni awọn ọmọ Simeoni fi ní ilẹ-iní lãrin ilẹ-iní wọn.

10. Ilẹ kẹta yọ fun awọn ọmọ Sebuluni gẹgẹ bi idile wọn: àla ilẹ-iní wọn si dé Saridi:

11. Àla wọn gòke lọ si ìha ìwọ-õrùn, ani titi o fi dé Marala, o si dé Dabaṣeti; o si dé odò ti mbẹ niwaju Jokneamu;

12. O si ṣẹri lati Saridi lọ ni ìha ìla-õrùn si ìla-õrùn dé àla Kisloti-tabori; o si yọ si Daberati; o si jade lọ si Jafia;

13. Ati lati ibẹ̀ o kọja ni ìha ìla-õrùn si Gati-heferi, dé Ẹti-kasini; o si yọ si Rimmoni titi o fi dé Nea;

14. Àla na si yi i ká ni ìha ariwa dé Hannatoni: o si yọ si afonifoji Ifta-eli;