Yorùbá Bibeli

Joṣ 17:3-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa.

4. Nwọn si wá siwaju Eleasari alufa, ati siwaju Joṣua ọmọ Nuni, ati siwaju awọn olori, wipe, OLUWA fi aṣẹ fun Mose lati fun wa ni ilẹ-iní lãrin awọn arakunrin wa: nitorina o fi ilẹ-iní fun wọn lãrin awọn arakunrin baba wọn, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA.

5. Ipín mẹwa si bọ́ sọdọ Manasse, làika ilẹ Gileadi ati Baṣani, ti mbẹ ni ìha keji Jordani;

6. Nitoriti awọn ọmọbinrin Manasse ní ilẹ-iní lãrin awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin: awọn ọmọ Manasse ọkunrin iyokù si ní ilẹ Gileadi.