Yorùbá Bibeli

Joṣ 16:2-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu;

3. O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun.

4. Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn.

5. Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke;

6. Àla na si lọ si ìha ìwọ-õrùn si ìha ariwa Mikmeta; àla na si yi lọ si ìha ìla-õrùn dé Taanati-ṣilo, o si kọja lẹba rẹ̀ lọ ni ìha ìla-õrùn Janoha;

7. O si sọkalẹ lati Janoha lọ dé Atarotu, ati dé Naara, o si dé Jeriko, o si yọ si Jordani.

8. Àla na jade lọ lati Tappua si ìha ìwọ-õrùn titi dé odò Kana; o si yọ si okun. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn;