Yorùbá Bibeli

Joṣ 13:25-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Àla wọn bẹ̀rẹ ni Jaseri, ati gbogbo ilu Gileadi, ati àbọ ilẹ awọn ọmọ Ammoni, titi dé Aroeri ti mbẹ niwaju Rabba;

26. Ati lati Heṣboni titi dé Ramatu-mispe, ati Betonimu; ati lati Mahanaimu titi dé àgbegbe Debiri;

27. Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn.

28. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Gadi gẹgẹ bi idile wọn, ilu wọn ati ileto wọn.

29. Mose si fi ilẹ-iní fun àbọ ẹ̀ya Manasse: o si jẹ́ ti àbọ ẹ̀ya awọn ọmọ Manasse gẹgẹ bi idile wọn.

30. Àla wọn si bẹ̀rẹ lati Mahanaimu lọ, gbogbo Baṣani, gbogbo ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani, ati gbogbo ilu Jairi, ti mbẹ ni Baṣani, ọgọta ilu:

31. Ati àbọ Gileadi, ati Aṣtarotu, ati Edrei, ilu ilẹ-ọba Ogu ni Baṣani, jẹ́ ti awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ani ti àbọ awọn ọmọ Makiri, gẹgẹ bi idile wọn.

32. Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn.

33. Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.