Yorùbá Bibeli

Joṣ 12:7-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Wọnyi li awọn ọba ilẹ na, ti Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa li apa ihin Jordani, ni ìwọ-õrùn, lati Baali-gadi li afonifoji Lebanoni ani titidé òke Halaki, li ọ̀na òke Seiri; ti Joṣua fi fun awọn ẹ̀ya Israeli ni ilẹ-iní gẹgẹ bi ipín wọn.

8. Ni ilẹ òke, ati ni ilẹ titẹju, ati ni pẹtẹlẹ̀, ati li ẹsẹ̀-òke, ati li aginjù, ati ni Gusù; awọn Hitti, awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, awọn Perissi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi:

9. Ọba Jeriko, ọkan; ọba Ai, ti o wà lẹba Beti-eli, ọkan.

10. Ọba Jerusalemu, ọkan; ọba Hebroni, ọkan;

11. Ọba Jarmutu, ọkan; ọba Lakiṣi, ọkan;

12. Ọba Egloni, ọkan; ọba Geseri, ọkan;

13. Ọba Debiri, ọkan; ọba Gederi, ọkan;

14. Ọba Horma, ọkan; ọba Aradi, ọkan;

15. Ọba Libna, ọkan; ọba Adullamu, ọkan;