Yorùbá Bibeli

3. Joh 1:9-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Emi kọwe si ijọ: ṣugbọn Diotrefe, ẹniti o fẹ lati jẹ olori larin wọn, kò gbà wa.

10. Nitorina bi mo ba de, emi o mu iṣẹ rẹ̀ ti o ṣe wá si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyini kò si tẹ́ ẹ lọrùn, bẹ̃ni on tikararẹ̀ kò gbà awọn ará, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o ndá wọn lẹkun, o si nlé wọn jade kuro ninu ijọ.

11. Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi, bikoṣe ohun ti iṣe rere. Ẹniti o ba nṣe rere ti Ọlọrun ni: ẹniti o ba nṣe buburu kò ri Ọlọrun.

12. Demetriu li ẹri rere lọdọ gbogbo enia ati ti otitọ tikararẹ̀ pẹlu: nitõtọ, awa pẹlu si gbà ẹrí rẹ̀ jẹ; ẹnyin si mọ̀ pe otitọ ni ẹrí wa.

13. Emi ní ohun pupọ̀ lati kọwe si ọ, ṣugbọn emi kò fẹ fi tàdãwa on kalamu kọ wọn.

14. Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju.

15. Alafia fun ọ. Awọn ọrẹ́ kí ọ. Kí awọn ọrẹ́ li ọkọ̃kan.