2. Tim

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4

Yorùbá Bibeli

2. Tim 3 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìwà tí Àwọn Eniyan Yóo Máa Hù ní Ọjọ́ Ìkẹyìn

1. ṢUGBỌN eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yio de.

2. Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnú, agberaga, asọ̀rọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ́,

3. Alainifẹ, alaile darijini, abanijẹ́, alaile-kó-ra-wọnnijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere,

4. Onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ fãji jù olufẹ Ọlọrun lọ;

5. Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sẹ́ agbara rẹ̀: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu.

6. Nitori ninu irú eyi li awọn ti nrakò wọ̀ inu ile, ti nwọn si ndì awọn obinrin alailọgbọn ti a dì ẹ̀ṣẹ rù ni igbekùn, ti a si nfi onirũru ifẹkufẹ fà kiri,

7. Nwọn nfi igbagbogbo kẹ́kọ, nwọn kò si le de oju ìmọ otitọ.

8. Njẹ gẹgẹ bi Janesi ati Jamberi ti kọ oju ija si Mose, bẹ̃li awọn wọnyi kọ oju ija si otitọ: awọn enia ti inu wọn dibajẹ, awọn ẹni ìtanù niti ọran igbagbọ́.

9. Ṣugbọn nwọn kì yio lọ siwaju jù bẹ̃lọ: nitori wère wọn yio farahan fun gbogbo enia gẹgẹ bi tiwọn ti yọri si.

A Tún Kìlọ̀ fún Timotiu

10. Ṣugbọn iwọ ti mọ̀ ẹkọ́ mi, igbesi aiye mi, ipinnu, igbagbọ́, ipamọra, ifẹ́ni, sũru,

11. Inunibini, iyà; awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo faradà: Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn.

12. Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini.

13. Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ.

14. Ṣugbọn iwọ duro ninu nkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣa si, ki iwọ ki o si mọ̀ ọdọ ẹniti iwọ gbé kọ́ wọn;

15. Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.

16. Gbogbo iwe-mimọ́ ti o ni imísi Ọlọrun li o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibani-wi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo:

17. Ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.