Yorùbá Bibeli

2. Tim 1:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nitorina máṣe tiju ẹrí Oluwa wa, tabi emi ondè rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alabapin ninu ipọnju ihinrere gẹgẹ bi agbara Ọlọrun;

9. Ẹniti o gbà wa là, ti o si fi ìpe mimọ́ pè wa, kì iṣe gẹgẹ bi iṣe wa, ṣugbọn gẹgẹ bi ipinnu ati ore-ọfẹ tirẹ̀, ti a fifun wa ninu Kristi Jesu lati aiyeraiye,

10. Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere,

11. Fun eyiti a yàn mi ṣe oniwasu, ati aposteli, ati olukọ.

12. Nitori idi eyiti emi ṣe njìya wọnyi pẹlu: ṣugbọn oju kò tì mi: nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì.

13. Dì apẹrẹ awọn ọ̀rọ ti o yè koro ti iwọ ti gbọ́ lọdọ mi mu, ninu igbagbọ́ ati ifẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.

14. Ohun rere nì ti a ti fi le ọ lọwọ, pa a mọ́ nipa Ẹmí Mimọ́ ti ngbe inu wa.

15. Eyi ni iwọ mọ̀, pe gbogbo awọn ti o wà ni Asia yipada kuro lẹhin mi; ninu awọn ẹniti Figellu ati Hermogene gbé wà.

16. Ki Oluwa ki o fi ãnu fun ile Onesiforu; nitoriti ima tù mi lara nigba pupọ̀, ẹ̀wọn mi kò si tì i loju:

17. Ṣugbọn nigbati o wà ni Romu, o fi ẹsọ̀ wá mi, o si ri mi.

18. Ki Oluwa ki o fifun u ki o le ri ãnu lọdọ Oluwa li ọjọ nì: iwọ tikararẹ sá mọ̀ dajudaju iye ohun ti o ṣe fun mi ni Efesu.