Yorùbá Bibeli

2. Sam 5:24-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Yìo si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lori awọn igi Baka na, nigbana ni iwọ o si yara, nitoripe nigbana li Oluwa yio jade lọ niwaju rẹ, lati kọlu ogun awọn Filistini.

25. Dafidi si ṣe bẹ̃, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun u; o si kọlu awọn Filistini lati Geba titi o fi de Gaseri.