Yorùbá Bibeli

2. Sam 3:22-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Si wõ, awọn iranṣẹ Dafidi ati Joabu si ti ibi ilepa ẹgbẹ ogun kan bọ̀, nwọn si mu ikogun pupọ bọ̀; ṣugbọn Abneri ko si lọdọ Dafidi ni Hebroni; nitoriti on ti rán a lọ: on si ti lọ li alafia.

23. Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia.

24. Joabu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Kini iwọ ṣe nì? wõ, Abneri tọ̀ ọ wá; ehatiṣe ti iwọ si fi rán a lọ? on si ti lọ.

25. Iwọ mọ̀ Abneri ọmọ Neri, pe, o wá lati tàn ọ jẹ, ati lati mọ̀ ijadelọ rẹ, ati ibọsile rẹ, ati lati mọ̀ gbogbo eyi ti iwọ nṣe.

26. Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀.

27. Abneri si pada si Hebroni, Joabu si ba a tẹ̀ larin oju ọ̀na lati ba a sọ̀rọ li alafia, o si gún u nibẹ labẹ inu, o si kú, nitori ẹjẹ Asaheli arakunrin rẹ̀.

28. Lẹhin igbati Dafidi si gbọ́ ọ, o si wipe, emi ati ijọba mi si jẹ alaiṣẹ niwaju Oluwa titi lai ni ẹjẹ Abneri ọmọ Neri:

29. Jẹ ki o wà li ori Joabu, ati li ori gbogbo idile baba rẹ̀; ki a má si fẹ ẹni ti o li arùn isun, tabi adẹtẹ, tabi ẹni ti ntẹ̀ ọpá, tabi, ẹniti a o fi idà pa, tabi ẹniti o ṣe alaili onjẹ kù ni ile Joabu.

30. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si pa Abneri, nitoripe on ti pa Asaheli arakunrin wọn ni Gibeoni li ogun.

31. Dafidi si wi fun Joabu ati fun gbogbo enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Ẹ fa aṣọ nyin ya, ki ẹnyin ki o si mu aṣọ-ọ̀fọ, ki ẹnyin ki o si sọkun niwaju Abneri. Dafidi ọba tikararẹ̀ si tẹle posi rẹ̀.

32. Nwọn si sin Abneri ni Hebroni: ọba si gbe ohùn rẹ̀ soke, o si sọkun ni iboji Abneri; gbogbo awọn enia na si sọkun.

33. Ọba si sọkun lori Abneri, o si wipe, Abneri iba ku iku aṣiwere?

34. A kò sa dè ọ li ọwọ́, bẹ̃ li a kò si kàn ẹsẹ rẹ li abà: gẹgẹ bi enia iti ṣubu niwaju awọn ikà enia, bẹ̃ni iwọ ṣubu. Gbogbo awọn enia na si tun sọkun lori rẹ̀.

35. Nigbati gbogbo enia si wá lati gbà Dafidi ni iyanju ki o jẹun nigbati ọjọ si mbẹ, Dafidi si bura wipe, Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati ju bẹ̃ lọ, bi emi ba tọ onjẹ wò, tabi nkan miran, titi õrun yio fi wọ̀.

36. Gbogbo awọn enia si kiyesi i, o si dara loju wọn: gbogbo eyi ti ọba ṣe si dara loju gbogbo awọn enia na.

37. Gbogbo awọn enia na ati gbogbo Israeli si mọ̀ lọjọ na pe, ki iṣe ifẹ ọba lati pa Abneri ọmọ Neri.

38. Ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin kò mọ̀ pe olori ati ẹni-nla kan li o ṣubu li oni ni Israeli?

39. Emi si ṣe alailagbara loni, bi o tilẹ jẹ pe a fi emi jọba; awọn ọkunrin wọnyi ọmọ Seruia si le jù mi lọ: Oluwa ni yio san a fun ẹni ti o ṣe ibi gẹgẹ bi ìwa buburu rẹ̀.