Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 8:22-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

22. Bẹ̃ni Edomu ṣọ̀tẹ kuro labẹ ọwọ Juda titi o fi di oni yi. Nigbana ni Libna ṣọ̀tẹ li akokò kanna.

23. Iyokù iṣe Joramu, ati gbogbo ohun ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

24. Joramu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i pẹlu awọn baba rẹ̀ ni ilu Dafidi: Ahasiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.