Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 24:3-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nitõtọ lati ẹnu Oluwa li eyi ti wá sori Juda, lati mu wọn kuro niwaju rẹ̀, nitori ẹ̀ṣẹ Manasse, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe;

4. Ati nitori ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ ti o ta silẹ pẹlu: nitoriti o fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kún Jerusalemu; ti Oluwa kò fẹ darijì.

5. Ati iyokù iṣe Jehoiakimu, ati gbogbo eyiti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

6. Bẹ̃ni Jehoiakimu sùn pẹlu awọn baba rẹ̀: Jehoiakini ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

7. Ọba Egipti kò si tun jade kuro ni ilẹ rẹ̀ mọ; nitori ọba Babeli ti gbà gbogbo eyiti iṣe ti ọba Egipti lati odò Egipti wá titi de odò Euferate.

8. Ẹni ọdun mejidilogun ni Jehoiakini nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li oṣù mẹta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Nehuṣta, ọmọbinrin Elnatani ti Jerusalemu.

9. On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti baba rẹ̀ ti ṣe.

10. Li akokò na, awọn iranṣẹ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá si Jerusalemu, a si dotì ilu na.