Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 12:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. LI ọdun keje Jehu ni Jehoaṣi bẹ̀rẹ si ijọba; ogoji ọdun li o si jọba ni Jerusalemu. Orukọ iyà rẹ̀ a mã jẹ Sibiah ti Beerṣeba.

2. Jehoaṣi si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa li ọjọ rẹ̀ gbogbo ninu eyiti Jehoiada alufa nkọ́ ọ.

3. Kiki ibi giga wọnni ni a kò mu kuro: awọn enia nrubọ, nwọn si nsun turari sibẹ ni ibi giga wọnni.

4. Jehoaṣi si wi fun awọn alufa pe, Gbogbo owo ti a yà si mimọ́ ti a si mu wá sinu ile Oluwa, ani olukuluku owo ti o kọja, ati owo idiyele olukuluku, ati gbogbo owo ti o ti inu ọkàn olukuluku wá lati mu wá sinu ile Oluwa.

5. Ẹ jẹ ki awọn alufa ki o mu u tọ̀ ara wọn, olukuluku lati ọwọ ojulùmọ rẹ̀: ẹ si jẹ ki nwọn ki o tun ẹya ile na ṣe, nibikibi ti a ba ri ẹya.

6. O si ṣe, li ọdun kẹtalelogun Jehoaṣi ọba, awọn alufa kò iti tun ẹya ile na ṣe.

7. Nigbana ni Jehoaṣi ọba pè Jehoiada alufa, ati awọn alufa miràn, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin kò tun ẹya ile na ṣe? njẹ nisisiyi ẹ máṣe gbà owo mọ lọwọ awọn ojulùmọ nyin, bikòṣepe ki ẹ fi i lelẹ fun ẹya ile na.

8. Awọn alufa si ṣe ilerí lati má gbà owo lọwọ awọn enia mọ, tabi lati má tun ẹya ile na ṣe.