Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 1:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni.

9. Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ.

10. Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.

11. On si tun rán olori-ogun ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, Bayi li ọba wi, yara sọ̀kalẹ.

12. Elijah si dahùn, o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o si run ọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọrun si sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.

13. O si tun rán olori-ogun ãdọta ekẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori-ogun ãdọta kẹta si gòke, o si wá, o si wolẹ lori ẽkún rẹ̀ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Iwọ, enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ́, jẹ ki ẹmi mi ati ẹmi awọn ãdọta ọmọ-ọdọ rẹ wọnyi, ki o ṣọwọn li oju rẹ.

14. Kiyesi i, iná sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run olori-ogun meji arãdọta iṣãju pẹlu arãdọta wọn: njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹmi mi ki o ṣọwọn li oju rẹ.

15. Angeli Oluwa si wi fun Elijah pe, Ba a sọ̀kalẹ lọ: máṣe bẹ̀ru rẹ̀. On si dide, o si ba a sọ̀kalẹ lọ sọdọ ọba.

16. On si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ ran onṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli lati bère ọ̀rọ rẹ̀? nitorina iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú;

17. Bẹ̃ni o kú gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti Elijah ti sọ. Jehoramu si jọba ni ipò rẹ̀, li ọdun keji Jehoramu ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda, nitoriti kò ni ọmọkunrin.

18. Ati iyokù iṣe Ahasiah ti o ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli?