Yorùbá Bibeli

2. A. Ọba 1:2-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ahasiah si ṣubu lãrin fèrese ọlọnà kan ni iyara òke rẹ̀ ti o wà ni Samaria, o si ṣàisan: o si rán awọn onṣẹ o si wi fun wọn pe, Ẹ lọ, ẹ bère lọwọ Baalsebubu, oriṣa Ekroni, bi emi o là ninu aisan yi.

3. Ṣugbọn angeli Oluwa wi fun Elijah, ara Tiṣbi pe, Dide, gòke lọ ipade awọn onṣẹ ọba Samaria, ki o si wi fun wọn pe, Kò ṣe pe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni ẹnyin fi nlọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni?

4. Njẹ nitorina bayi li Oluwa wi, Iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì lori eyiti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú. Elijah si lọ kuro.

5. Nigbati awọn onṣẹ si pada si ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi pada sẹhin?

6. Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan li o gòke lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ pada tọ̀ ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? nitorina, iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú.

7. On si wi fun wọn pe, Iru ọkunrin wo li ẹniti o gòke lati pade nyin, ti o si sọ̀rọ wọnyi fun nyin?

8. Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni.

9. Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ.

10. Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.