21. Mo si dide li owurọ lati fi ọmú fun ọmọ mi, si wò o, o ti kú: ṣugbọn nigbati mo wò o fin li owurọ̀, si wò o, kì iṣe ọmọ mi ti mo bí.
22. Obinrin keji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi alãye ni ọmọ mi, eyi okú li ọmọ rẹ, eyi si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye si li ọmọ mi. Bayi ni nwọn nsọ niwaju ọba.
23. Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi.
24. Ọba si wipe, Ẹ mu idà fun mi wá. Nwọn si mu idà wá siwaju ọba.