Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 22:42-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Jehoṣafati si to ẹni ọdun marundilogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba; o si jọba ọdun mẹ̃dọgbọn ni Jerusalẹmu. Orukọ iya rẹ̀ ni Asuba ọmọbinrin Ṣilhi.

43. O si rin ni gbogbo ọ̀na Asa baba rẹ̀; kò yipada kuro ninu rẹ̀, o nṣe eyiti o tọ li oju Oluwa: kiki a kò mu awọn ibi giga kuro; awọn enia si nrú ẹbọ, nwọn si nsun turari sibẹ̀ ni ibi giga wọnni.

44. Jehoṣafati si wà li alafia pẹlu ọba Israeli.

45. Ati iyokù iṣe Jehoṣafati ati iṣe agbara rẹ̀ ti o ṣe, ati bi o ti jagun si, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?

46. Iyokù awọn ti nhuwà panṣaga ti o kù li ọjọ Asa baba rẹ̀, li o parun kuro ni ilẹ na.

47. Nigbana kò si ọba ni Edomu: adelé kan li ọba.

48. Jehoṣafati kàn ọkọ̀ Tarṣiṣi lati lọ si Ofiri fun wura; ṣugbọn nwọn kò lọ: nitori awọn ọkọ̀ na fọ́ ni Esion-Geberi.