Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 22:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Bẹ̃ni o de ọdọ ọba. Ọba si wi fun u pe, Mikaiah, ki awa o ha lọ si Ramoti-Gileadi lọ ijagun, tabi ki a jọwọ rẹ̀? O si da a lohùn pe, Lọ, ki o si ṣe rere: nitori Oluwa yio fi i le ọba lọwọ.

16. Ọba si wi fun u pe, Igba melo li emi o fi ọ bu pe, ki iwọ ki o máṣe sọ ohun kan fun mi bikoṣe otitọ li orukọ Oluwa?

17. On si wipe, Mo ri gbogbo Israeli tukakiri lori awọn oke bi agutan ti kò ni oluṣọ: Oluwa si wipe, Awọn wọnyi kò ni oluwa, jẹ ki nwọn ki o pada olukuluku si ile rẹ̀ li alafia.

18. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, Emi kò sọ fun ọ, pe on kì o fọ̀ ire si mi, bikoṣe ibi?

19. On si wipe, Nitorina, iwọ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Mo ri Oluwa joko lori itẹ́ rẹ̀, ati gbogbo ogun-ọrun duro li apa ọtun ati li apa òsi rẹ̀.

20. Oluwa si wipe, Tani yio tàn Ahabu, ki o le goke lọ, ki o si le ṣubu ni Ramoti-Gileadi? Ẹnikan si wi bayi, ẹlomiran si sọ miran.

21. Ẹmi kan si jade wá, o si duro niwaju Oluwa, o si wipe, Emi o tàn a.

22. Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃.

23. Njẹ nisisiyi, kiyesi i, Oluwa ti fi ẹmi-eke si ẹnu gbogbo awọn woli rẹ wọnyi, Oluwa si ti sọ ibi si ọ.