Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 2:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ṣugbọn ki o ṣe ore fun awọn ọmọ Barsillai, ara Gileadi, ki o si jẹ ki nwọn ki o wà ninu awọn ti o jẹun lori tabili rẹ: nitori bẹ̃ni nwọn ṣe tọ̀ mi wá nigbati mo sá kuro niwaju Absalomu, arakunrin rẹ.

8. Si wò o, Ṣimei, ọmọ Gera, ẹyà Benjamimi ti Bahurimu, wà pelu rẹ ti o bú mi ni ẽbu ti o burujù, ni ọjọ́ ti mo lọ si Mahanaimu: ṣugbọn o sọkalẹ wá pade mi ni Jordani, mo si fi Oluwa bura fun u pe, Emi kì yio fi idà pa ọ.

9. Ṣugbọn nisisiyi, máṣe jẹ ki o ṣe alaijiya, nitori ọlọgbọ́n enia ni iwọ, iwọ si mọ̀ ohun ti iwọ o ṣe si i; ṣugbọn ewú ori rẹ̀ ni ki o mu sọkalẹ pẹlu ẹjẹ sinu isa-okú.

10. Dafidi si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ni ilu Dafidi.

11. Ọjọ ti Dafidi jọba lori Israeli jẹ ogoji ọdun: ni Hebroni o jọba li ọdun meje, ni Jerusalemu o si jọba li ọdun mẹtalelọgbọn.

12. Solomoni si joko lori itẹ Dafidi baba rẹ̀; a si fi idi ijọba rẹ̀ kalẹ gidigidi.

13. Adonijah, ọmọ Haggiti si tọ Batṣeba, iya Solomoni wá, Batṣeba si wipe; Alafia li o ba wá bi? On si wipe, alafia ni.

14. On si wipe, emi ni ọ̀rọ kan ba ọ sọ. On si wipe, Mã wi:

15. On si wipe, Iwọ mọ̀ pe, ijọba na ti emi ni ri, ati pe, gbogbo Israeli li o fi oju wọn si mi lara pe, emi ni o jọba: ṣugbọn ijọba na si yí, o si di ti arakunrin mi; nitori tirẹ̀ ni lati ọwọ́ Oluwa wá.

16. Nisisiyi, ibere kan ni mo wá bere lọwọ rẹ, máṣe dù mi: O si wi fun u pe, Mã wi.

17. O si wi pe, Mo bẹ ọ, sọ fun Solomoni ọba (nitori kì yio dù ọ,) ki o fun mi ni Abiṣagi, ara Ṣunemu li aya.

18. Batṣeba si wipe, o dara; emi o ba ọba sọrọ nitori rẹ.