Yorùbá Bibeli

1. A. Ọba 12:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. O si wi fun wọn pe, Imọran kini ẹnyin dá ki awa ki o le dá awọn enia yi lohùn, ti nwọn ba mi sọ wipe, Ṣe ki àjaga ti baba rẹ fi si wa lọrùn ki o fuyẹ diẹ?

10. Awọn ipẹrẹ ti o dagba pẹlu rẹ̀ wi fun u pe, Bayi ni ki iwọ ki o wi fun awọn enia yi ti nwọn ba ọ sọ wipe, Baba rẹ mu ki àjaga wa di wuwo, sugbọn iwọ mu ki o fuyẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o sọ fun wọn: ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.

11. Njẹ nisisiyi, baba mi ti gbe àjaga wuwo kà nyin, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi ti fi paṣan nà nyin, sugbọn emi o fi akẽke nà nyin.

12. Bẹ̃ni Jeroboamu ati gbogbo awọn enia na wá sọdọ Rehoboamu ni ijọ kẹta, gẹgẹ bi ọba ti dá wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.

13. Ọba si da awọn enia li ohùn akọ, o si kọ̀ ìmọran awọn àgbagba ti nwọn ba a dá.

14. O si sọ fun wọn gẹgẹ bi ìmọran awọn ipẹrẹ wipe, Baba mi mu ki àjaga nyin ki o wuwo, emi o si bù kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin,

15. Ọba kò si fi eti si ti awọn enia na; nitoriti ọ̀ran na ati ọwọ Oluwa wá ni, ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti Oluwa ti ọwọ Ahijah, ara Ṣilo, sọ fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.

16. Bẹ̃ni nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kò fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba li ohùn wipe: Ipin kini awa ni ninu Dafidi? bẹ̃ni awa kò ni iní ninu ọmọ Jesse: Israeli, ẹ pada si agọ nyin: njẹ mã bojuto ile rẹ, Dafidi! Bẹ̃ni Israeli pada sinu agọ wọn.

17. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe inu ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.

18. Nigbana ni Rehoboamu ọba, ran Adoramu ẹniti iṣe olori iṣẹ-iru; gbogbo Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Nitorina Rehoboamu, ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀, lati sá lọ si Jerusalemu.

19. Bẹ̃ni Israeli ṣọtẹ̀ si ile Dafidi titi di oni yi.