Yorùbá Bibeli

Esr 8:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI ni awọn olori ninu awọn baba wọn, eyi ti a kọ sinu iwe itan-idile awọn ti o ba mi goke lati Babiloni wá, ni ijọba Artasasta ọba.

2. Ninu awọn ọmọ Finehasi, Gerṣomu: ninu awọn ọmọ Itamari, Danieli: ninu awọn ọmọ Dafidi, Hattuṣi.

3. Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah, ti awọn ọmọ Paroṣi, Ṣekariah: ati pẹlu rẹ̀ li a ka ãdọjọ ọkunrin nipa iwe itan-idile.

4. Ninu awọn ọmọ Pahat-moabu; Elihoenai ọmọ Serahiah, ati pẹlu rẹ̀, igba ọkunrin.

5. Ninu awọn ọmọ Ṣekaniah; ọmọ Jahasieli, ati pẹlu rẹ̀, ọdunrun ọkunrin.

6. Ninu awọn ọmọ Adini pẹlu, Ebedi ọmọ Jonatani, ati pẹlu rẹ̀, ãdọta ọkunrin.

7. Ati ninu awọn ọmọ Elamu; Jeṣaiah ọmọ Ataliah, ati pẹlu rẹ̀, ãdọrin ọkunrin.

8. Ati ninu awọn ọmọ Ṣefatiah; Sebadiah ọmọ Mikaeli, ati pẹlu rẹ̀, ọgọrin ọkunrin.

9. Ninu awọn ọmọ Joabu; Obadiah ọmọ Jahieli ati pẹlu rẹ̀, ogunlugba ọkunrin o din meji.

10. Ati ninu awọn ọmọ Ṣelomiti; ọmọ Josafiah, ati pẹlu rẹ̀, ọgọjọ ọkunrin.

11. Ati ninu awọn ọmọ Bebai; Sekariah, ọmọ Bebai, ati pẹlu rẹ̀, ọkunrin mejidilọgbọn.