Yorùbá Bibeli

Esr 2:61-70 Yorùbá Bibeli (YCE)

61. Ati ninu awọn ọmọ awọn alufa: awọn ọmọ Habaiah, awọn ọmọ Hakosi, awọn ọmọ Barsillai, ti o fẹ ọkan ninu awọn ọmọ Barsillai obinrin, ara Gileadi li aya, a si pè e nipa orukọ wọn;

62. Awọn wọnyi li o wá iwe itan wọn ninu awọn ti a ṣiro nipa itan idile, ṣugbọn a kò ri wọn, nitori na li a ṣe yọ wọn kuro ninu oye alufa.

63. Balẹ si wi fun wọn pe, ki nwọn ki o má jẹ ninu ohun mimọ́ julọ, titi alufa kan yio fi dide pẹlu Urimu ati pẹlu Tummimu.

64. Apapọ gbogbo ijọ na, jẹ ẹgbã mọkanlelogun o le ojidinirinwo.

65. Li aika iranṣẹkunrin wọn ati iranṣẹbinrin wọn, ti o jẹ ẹgbẹrindilẹgbãrin o din mẹtalelọgọta: igba akọrin ọkunrin ati akọrin obinrin li o si wà ninu wọn.

66. Ẹṣin wọn jẹ, ọtadilẹgbẹrin o din mẹrin; ibaka wọn, ojilugba o le marun.

67. Ibakasiẹ wọn, irinwo o le marundilogoji; kẹtẹkẹtẹ wọn, ẹgbẹrinlelọgbọn o din ọgọrin.

68. Ati ninu awọn olori awọn baba, nigbati nwọn de ile Oluwa ti o wà ni Jerusalemu, nwọn si ta ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun, lati gbe e duro ni ipò rẹ̀.

69. Nwọn fi sinu iṣura iṣẹ na gẹgẹ bi agbara wọn, ọkẹ mẹta ìwọn dramu wura, o le ẹgbẹrun, ẹgbẹdọgbọn mina fadaka, ati ọgọrun ẹ̀wu alufa.

70. Bẹ̃li awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, ati omiran ninu awọn enia, ati awọn akọrin, ati awọn adèna, ati awọn Netinimu ngbe ilu wọn, gbogbo Israeli si ngbe ilu wọn.