Yorùbá Bibeli

Esr 10:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NIGBATI Esra ti gba adura, ti o si jẹwọ pẹlu ẹkún ati idojubolẹ niwaju ile Ọlọrun, ijọ enia pupọ kó ara wọn jọ si ọdọ rẹ̀ lati inu Israeli jade, ati ọkunrin ati obinrin ati ọmọ wẹwẹ: nitori awọn enia na sọkun gidigidi.

2. Ṣekaniah ọmọ Jehieli, lati inu awọn ọmọ Elamu dahùn o si wi fun Esra pe, Awa ti ṣẹ̀ si Ọlọrun wa, ti awa ti mu ajeji obinrin lati inu awọn enia ilẹ na: sibẹ, ireti mbẹ fun Israeli nipa nkan yi.

3. Njẹ nitorina ẹ jẹ ki awa ki o ba Ọlọrun wa da majẹmu, lati kọ̀ gbogbo awọn obinrin na silẹ, ati iru awọn ti nwọn bi gẹgẹ bi ìmọ (Esra) oluwa mi, ati ti awọn ti o wariri si aṣẹ Ọlọrun wa: ki awa ki o si mu u ṣẹ gẹgẹ bi ofin na.

4. Dide! nitori ọran tirẹ li eyi: awa pãpã yio wà pẹlu rẹ, mu ọkàn le ki o si ṣe e.

5. Esra si dide, o si mu awọn olori ninu awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, ati gbogbo Israeli bura pe, awọn o ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi. Nwọn si bura.

6. Esra si dide kuro niwaju ile Ọlọrun, o si wọ̀ yara Johanani ọmọ Eliaṣibu lọ: nigbati o si lọ si ibẹ, on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi: nitoripe o nṣọ̀fọ nitori irekọja awọn ti a kó lọ.

7. Nwọn si kede ja gbogbo Juda ati Jerusalemu fun gbogbo awọn ọmọ igbèkun, ki nwọn ki o kó ara wọn jọ pọ̀ si Jerusalemu;

8. Ati pe ẹnikẹni ti kò ba wá niwọ̀n ijọ mẹta, gẹgẹ bi ìmọ awọn olori ati awọn agba, gbogbo ini rẹ̀ li a o jẹ, on tikararẹ̀ li a o si yà kuro ninu ijọ awọn enia ti a ti ko lọ.