Yorùbá Bibeli

Esr 1:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Tani ninu nyin ninu gbogbo enia rẹ̀? ki Ọlọrun rẹ̀ ki o wà pẹlu rẹ̀, ki o si goke lọ si Jerusalemu, ti o wà ni Juda, ki o si kọ ile OLUWA Ọlọrun Israeli, on li Ọlọrun, ti o wà ni Jerusalemu.

4. Ati ẹnikẹni ti o kù lati ibikibi ti o ti ngbe, ki awọn enia ibugbe rẹ̀ ki o fi fadaka ràn a lọwọ, pẹlu wura, ati pẹlu ẹrù, ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, pẹlu ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu.

5. Nigbana ni awọn olori awọn baba Juda ati Benjamini dide, ati awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu gbogbo awọn ẹniti Ọlọrun rú ẹmi wọn soke, lati goke lọ, lati kọ́ ile OLUWA ti o wà ni Jerusalemu.

6. Gbogbo awọn ti o wà li agbegbe wọn si fi ohun-èlo fadaka ràn wọn lọwọ, pẹlu wura, pẹlu ẹrù ati pẹlu ẹran-ọ̀sin, ati pẹlu ohun iyebiye, li aika gbogbo ọrẹ atinuwa.

7. Kirusi ọba si ko ohun èlo ile OLUWA jade, ti Nebukadnessari ti ko jade lọ lati Jerusalemu, ti o si fi sinu ile ọlọrun rẹ̀;

8. Kirusi ọba Persia si ko wọnyi jade nipa ọwọ Mitredati, oluṣọ iṣura, o si ka iye wọn fun Ṣeṣbassari (Serubbabeli) bãlẹ Juda.

9. Iye wọn si li eyi: ọgbọn awo-pọ̀kọ wura, ẹgbẹrun awo-pọ̀kọ fadaka, ọbẹ mọkandilọgbọn,

10. Ọgbọn ago wura, ago fadaka iru ekeji, irinwo o le mẹwa, ohun èlo miran si jẹ ẹgbẹrun.

11. Gbogbo ohun-èlo wura ati ti fadaka jẹ ẹgbẹtadilọgbọn. Gbogbo wọnyi ni Ṣeṣbassari mu goke wá pẹlu awọn igbekun ti a mu goke lati Babiloni wá si Jerusalemu.