Yorùbá Bibeli

Eks 40:28-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. O si ta aṣọ-isorọ̀ nì si ẹnu-ọ̀na agọ́ na.

29. O si fi pẹpẹ ẹbọsisun si ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ, o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

30. O si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, o si pọn omi si i, lati ma fi wẹ̀.

31. Ati Mose ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wẹ̀ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn ninu rẹ̀.

32. Nigbati nwọn ba lọ sinu agọ́ ajọ, ati nigbati nwọn ba sunmọ pẹpẹ na, nwọn a wẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

33. O si fà agbalá na yi agọ́ ati pẹpẹ na ká, o si ta aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na. Bẹ̃ni Mose pari iṣẹ na.

34. Nigbana li awọsanma bò agọ́ ajọ, ogo OLUWA si kún inu agọ́ na.

35. Mose kò si le wọ̀ inu agọ́ ajọ lọ, nitoriti awọsanma wà lori rẹ̀, ogo OLUWA si kun inu agọ́ na.

36. Nigbati a si fà awọsanma na soke, kuro lori agọ́ na, awọn ọmọ Israeli a ma dide rìn lọ ni ìrin wọn gbogbo:

37. Ṣugbọn bi a kò fà awọsanma na soke, njẹ nwọn kò ni idide rìn titi ọjọ-kọjọ́ ti o ba fà soke.

38. Nitoriti awọsanma OLUWA wà lori agọ́ na li ọsán, iná si wà ninu awọsanma na li oru, li oju gbogbo ile Israeli, ni gbogbo ìrin wọn.