Yorùbá Bibeli

Eks 40:18-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Mose si gbé agọ́ na ró, o si de ihò-ìtẹbọ rẹ̀, o si tò apáko rẹ̀, o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ, o si gbé ọwọ̀n rẹ̀ ró.

19. O si nà aṣọ agọ́ na sori agọ́, o si fi ibori agọ́ na bò o li ori; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

20. O si mú, o si fi ẹrí nì sinu apoti na, o si fi ọpá wọnni sara apoti na, o si fi itẹ́-ãnu nì si oke lori apoti na:

21. O si gbé apoti na wá sinu agọ́, o si ta aṣọ-ikele, o si ta a bò apoti ẹrí; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

22. O si fi tabili nì sinu agọ́ ajọ, ni ìha ariwa agọ́ na, lẹhin ode aṣọ-ikele nì.

23. O si tò àkara na lẹ̀sẹsẹ daradara lori rẹ̀ niwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

24. O si fi ọpá-fitila nì sinu agọ́ ajọ, ki o kọjusi tabili nì ni ìha gusù agọ na.

25. O si tàn fitila wọnni siwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

26. O si fi pẹpẹ wurà nì sinu agọ́ ajọ niwaju aṣọ-ikele nì:

27. O si fi turari didùn joná lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

28. O si ta aṣọ-isorọ̀ nì si ẹnu-ọ̀na agọ́ na.

29. O si fi pẹpẹ ẹbọsisun si ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ, o si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ ohunjijẹ lori rẹ̀; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

30. O si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, o si pọn omi si i, lati ma fi wẹ̀.

31. Ati Mose ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wẹ̀ ọwọ́ ati ẹsẹ̀ wọn ninu rẹ̀.