Yorùbá Bibeli

Eks 40:11-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Iwọ o si ta oróro sara agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́.

12. Iwọ o si mú Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn.

13. Iwọ o si fi aṣọ mimọ́ wọnni wọ̀ Aaroni; iwọ o si ta oróro si i li ori, iwọ o si yà a simimọ́, ki o le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi.

14. Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá, iwọ o si fi ẹ̀wu wọ̀ wọn:

15. Iwọ o si ta oróro si wọn li ori, bi iwọ ti ta si baba wọn li ori, ki nwọn ko le ma ṣe iṣẹ alufa fun mi: nitoriti itasori wọn yio jẹ́ iṣẹ-alufa lailai nitõtọ, lati irandiran wọn.

16. Bẹ̃ni Mose ṣe: gẹgẹ bi eyiti OLUWA palaṣẹ fun u, bẹ̃li o ṣe.

17. O si ṣe li oṣù kini li ọdún keji ni ijọ́ kini oṣù na, ni a gbé agọ́ na ró.

18. Mose si gbé agọ́ na ró, o si de ihò-ìtẹbọ rẹ̀, o si tò apáko rẹ̀, o si fi ọpá rẹ̀ bọ̀ ọ, o si gbé ọwọ̀n rẹ̀ ró.

19. O si nà aṣọ agọ́ na sori agọ́, o si fi ibori agọ́ na bò o li ori; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

20. O si mú, o si fi ẹrí nì sinu apoti na, o si fi ọpá wọnni sara apoti na, o si fi itẹ́-ãnu nì si oke lori apoti na:

21. O si gbé apoti na wá sinu agọ́, o si ta aṣọ-ikele, o si ta a bò apoti ẹrí; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

22. O si fi tabili nì sinu agọ́ ajọ, ni ìha ariwa agọ́ na, lẹhin ode aṣọ-ikele nì.

23. O si tò àkara na lẹ̀sẹsẹ daradara lori rẹ̀ niwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

24. O si fi ọpá-fitila nì sinu agọ́ ajọ, ki o kọjusi tabili nì ni ìha gusù agọ na.

25. O si tàn fitila wọnni siwaju OLUWA; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.