Yorùbá Bibeli

Eks 40:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Li ọjọ́ kini oṣù kini ni ki iwọ ki o gbé ibugbé agọ́ na ró.

3. Iwọ o si fi apoti ẹrí nì sinu rẹ̀, iwọ o si ta aṣọ-ikele ni bò apoti na.

4. Iwọ o si gbé tabili wọle, ki o si tò ohun wọnni ti o ni itò si ori rẹ̀; iwọ o si mú ọpá-fitila wọle, iwọ o si tò fitila rẹ̀ wọnni lori rẹ̀.

5. Iwọ o si fi pẹpẹ wurà ti turari nì si iwaju apoti ẹrí, iwọ o si fi aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na sara agọ́ na.

6. Iwọ o si fi pẹpẹ ẹbọsisun nì si iwaju ẹnu-ọ̀na ibugbé agọ́ ajọ.

7. Iwọ o si gbé agbada nì kà agbede-meji agọ́ ajọ ati pẹpẹ, iwọ o si pọn omi sinu rẹ̀.

8. Iwọ o si fà agbalá na yiká, iwọ o si ta aṣọ-isorọ̀ si ẹnu-ọ̀na agbalá na.

9. Iwọ o si mù oróro itasori nì, iwọ o si ta a sara agọ́ na, ati sara ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀: yio si jẹ́ mimọ́.

10. Iwọ o si ta oróro sara pẹpẹ ẹbọsisun, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, iwọ o si yà pẹpẹ na simimọ́: yio si ma jẹ́ pẹpẹ ti o mọ́ julọ.

11. Iwọ o si ta oróro sara agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀, iwọ o si yà a simimọ́.