Yorùbá Bibeli

Eks 39:25-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nwọn si ṣe ṣaworo kìki wurà, nwọn si fi ṣaworo na si alafo pomegranate wọnni si eti iṣẹti aṣọ igunwa na, yiká li alafo pomegranate wọnni;

26. Ṣaworo kan ati pomegranate kan, ṣaworo kan ati pomegranate kan, yi iṣẹti aṣọ-igunwa na ká lati ma fi ṣiṣẹ alufa; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

27. Nwọn si ṣe ẹ̀wu ọ̀gbọ daradara ti iṣẹ híhun fun Aaroni, ati fun awọn ọmo rẹ̀,

28. Ati fila ọṣọ́ ọ̀gbọ daradara, ati fila ọ̀gbọ didara, ati ṣòkoto ọ̀gbọ olokún wiwẹ,

29. Ati ọjá ọ̀gbọ olokùn wiwẹ́, ati ti aṣọ-alaró, ti elesè-àluko, ati ti ododo, oniṣẹ abẹ́rẹ; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.

30. Nwọn si ṣe awo adé mimọ́ na ni kìki wurà, nwọn si kọwe si i, ikọwe bi fifin èdidi-àmi, MIMỌ SI OLUWA.

31. Nwọn si dì ọjá àwọn alaró mọ́ ọ, lati fi dì i loke sara fila na; bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.

32. Bẹ̃ni gbogbo iṣẹ agọ́ ti agọ́ ajọ na pari: awọn ọmọ Israeli si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA palaṣẹ fun Mose, bẹ̃ni nwọn ṣe.

33. Nwọn si mú agọ́ na tọ̀ Mose wá, agọ́ na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ikọ́ rẹ̀, apáko rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, ati ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀ wọnni;

34. Ati ibori awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati ibori awọ seali, ati ikele aṣọ-tita.

35. Apoti ẹrí nì, ati ọpá rẹ̀ wọnni, ati itẹ́-ãnu nì;

36. Tabili na, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati àkara ifihàn;

37. Ọpá-fitila mimọ́, pẹlu fitila rẹ̀ wọnni, fitila ti a tò li ẹsẹ̀-ẹsẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, ati oróro titanna;

38. Ati pẹpẹ wurà, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agọ́ na;

39. Pẹpẹ idẹ, ati oju-àro-àwọn idẹ rẹ̀, ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo rẹ̀, agbada na ati ẹsẹ̀ rẹ̀;

40. Aṣọ-tita agbalá na, ọwọ̀n rẹ̀ ati ihò-ìtẹbọ̀ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ ẹnu-ọ̀na agbalá na, okùn rẹ̀, ati ekàn rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo ìsin agọ́ na, ani agọ́ ajọ;

41. Aṣọ ìsin lati ma fi sìn ninu ibi mimọ́, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa.

42. Gẹgẹ bi gbogbo ohun ti OLUWA fi aṣẹ fun Mose, bẹ̃li awọn ọmọ Israeli ṣe gbogbo iṣẹ na.