Yorùbá Bibeli

Eks 33:6-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Awọn ọmọ Israeli si bọ́ ohun ọṣọ́ wọn kuro lara wọn leti oke Horebu.

7. Mose si mú agọ́ na, o si pa a lẹhin ibudó, li òkere rére si ibudó; o pè e ni Agọ́ ajọ. O si ṣe, olukuluku ẹniti mbère OLUWA o jade lọ si agọ́ ajọ, ti o wà lẹhin ibudó.

8. O si ṣe, nigbati Mose jade lọ si ibi agọ́ na, gbogbo awọn enia a si dide duro, olukuluku a si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ rẹ̀, a ma wò ẹhin Mose, titi yio fi dé ibi agọ́ na.

9. O si ṣe, bi Mose ti dé ibi agọ́ na, ọwọ̀n awọsanma sọkalẹ, o si duro li ẹnu-ọ̀na agọ́ na: OLUWA si bá Mose sọ̀rọ.