Yorùbá Bibeli

Eks 30:27-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. Ati tabili ati ohunèlo rẹ̀ gbogbo, ati ọpáfitila ati ohun-èlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari,

28. Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada ati ẹsẹ̀ rẹ̀.

29. Iwọ o si yà wọn simimọ́, ki nwọn ki o le ṣe mimọ́ julọ: ohunkohun ti o ba fọwọkàn wọn yio di mimọ́.

30. Iwọ o si ta òróró sí Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si yà wọn si mimọ́, ki nwọn ki o le ma ṣe alufa fun mi.

31. Iwọ o si sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Eyi ni yio ma ṣe oróro mimọ́ itasori fun mi lati irandiran nyin.

32. A ko gbọdọ dà a si ara enia, bẹ̃li ẹnyin kò gbọdọ ṣe irú rẹ̀, ni ìwọn pipò rẹ̀: mimọ́ ni, yio si ma ṣe mimọ́ fun nyin.

33. Ẹnikẹni ti o ba pò bi irú rẹ̀, tabi ẹnikẹni ti o ba fi sara alejò ninu rẹ̀, on li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

34. OLUWA si wi fun Mose pe, Mú olõrùn didùn sọdọ rẹ, stakte, ati onika, ati galbanumu; olõrùn didùn wọnyi, pẹlu turari daradara: òṣuwọn kan na li olukuluku;

35. Iwọ o si ṣe e ni turari, apòlu nipa ọgbọ́n-ọnà alapòlu, ti a fi iyọ̀ si, ti o dara ti o si mọ́.

36. Iwọ o si gún diẹ ninu rẹ̀ kunna, iwọ o si fi i siwaju ẹrí ninu rẹ̀ ninu agọ́ ajọ, nibiti emi o gbé ma bá ọ pade: yio ṣe mimọ́ julọ fun nyin.

37. Ati ti turari ti iwọ o ṣe, ẹnyin kò gbọdọ ṣe e fun ara nyin ni ìwọn pipò rẹ̀: yio si ṣe mimọ́ fun ọ si OLUWA.

38. Ẹnikẹni ti o ba ṣe irú rẹ̀, lati ma gbõrùn rẹ̀, on li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.